Ezekiel 7:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba yio ṣọ̀fọ, a o si fi idahoro wọ̀ ọmọ-alade, ọwọ́ awọn enia ilẹ na li a o wahala, emi o ṣe si wọn gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi ẹjọ wọn ti ri li emi o dá a fun wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba yóò sọ̀fọ̀, ọmọ aláde yóò wà láì ní ìrètí ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn, nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLÚWA.”