Ezekiel 7:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò sì ní ṣàánú yín. Ṣugbọn n óo jẹ yín níyà fún gbogbo ìwà yín níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ṣugbọn emi o san ọ̀na rẹ pada si ọ lori, ati irira rẹ yio wà li ãrin rẹ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú mi kò ní i dá ọ sì bẹ́ẹ̀ ni ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ṣùgbọ́n ń ó san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.