Ezekiel 7:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò ní ṣàánú yín. N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA, ni mò ń jẹ yín níyà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: emi o si san fun ọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati irira rẹ ti mbẹ lãrin rẹ; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa ti nkọlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú mi kò ní i dá ọ sí, ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ń o san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà ìwà àti gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi OLÚWA lo kọlù yín.