Ezekiel 8:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, li ọdun ẹkẹfa, li oṣù ẹkẹfa, li ọjọ karun oṣù, bi mo ti joko ni ile mi, ti awọn àgbagba Juda si joko niwaju mi, ni ọwọ́ Oluwa Ọlọrun bà le mi nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ karùn-ún (5), oṣù kẹfà (6) ọdún kẹfà (6) bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júdà níwájú mi, ọwọ́ OLÚWA Ọlọ́run bà lé mi níbẹ̀.