Ezekiel 8:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adọrin ọkunrin ninu awọn agbà ile Israeli si duro niwaju wọn, Jaasania ọmọ Ṣafani si duro lãrin wọn, olukuluku pẹlu awo turari lọwọ rẹ̀; ẹ̃fin ṣiṣu dùdu ti turari si goke lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbà ilé Ísírẹ́lì dúró sí, Jáásáníà ọmọ Sáfánì sì dúró sáàrin wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.