Ezekiel 8:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu mi wá si inu agbala ile Oluwa, si kiye si i, li ẹnu-ọ̀na tempili Oluwa, lãrin iloro ati pẹpẹ, ni iwọ̀n ọkunrin mẹ̃dọgbọ̀n wà, ti nwọn kẹ̀hin si tẹmpili Oluwa, ti nwọn si kọju si ila-õrùn; nwọn si foribalẹ fun õrun si ila-õrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé OLÚWA, lẹ́nu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì OLÚWA, wọn kọjú sí ìlà òòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún òòrùn ní apá ìlà òòrùn.