Ezekiel 8:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o wi fun mi pe, Iwọ ri eyi, ọmọ enia? ohun kekere ni fun ile Juda lati ṣe ohun irira ti nwọn nṣe nihin? nitori nwọn fi ìwa-ipa kún ilẹ na, nwọn si ti pada lati mu mi binu, si kiye si i, nwọn tẹ̀ ẹka-igi bọ imú wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún mi, “Ṣé o ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékéré ni fún ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé ó tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn se n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn.