Ezekiel 8:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, iwọ ri ohun ti nwọn nṣe? ani irira nla ti ile Israeli nṣe nihinyi, ki emi ba le lọ jina kuro ni ibi mimọ́ mi? ṣugbọn si tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o jù wọnyi lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe-ohun ìríra ńlá tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ ó tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù yí lọ.”