Ezekiel 9:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wò ó! Mo bá rí àwọn ọkunrin mẹfa kan tí wọn ń bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà òkè tí ó kọjú sí ìhà àríwá. Olukuluku mú ohun ìjà tí ó fẹ́ fi pa eniyan lọ́wọ́. Ọkunrin kan wà láàrin wọn tí ó wọ aṣọ funfun, ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. Wọ́n wọlé, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, ọkunrin mẹfa jade lati ẹnu ilẹkun oke wá, ti o wà niha ariwa, olukuluku ton ti ohun-ijà ipani li ọwọ́ rẹ̀: ọkunrin kan ninu wọn si wọ aṣọ ọgbọ̀, pẹlu ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: nwọn si wọ inu ile, nwọn si duro lẹba pẹpẹ idẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà (6) jáde láti ẹnu ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun lẹlẹ wa láàrin wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀we lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.