Ezekiel 9:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun u pe, La ãrin ilu já, li ãrin Jerusalemu, ki o si sami si iwaju awọn ọkunrin ti nkẹdùn, ti nwọn si nkigbe nitori ohun irira ti nwọn nṣe lãrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì sọ fún un pé, “La àárin ìlú Jérúsálẹ́mù já, kí o sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sunkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrin rẹ̀.”