Ezekiel 9:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ pa arugbo ati ọmọde patapata, awọn wundia ati ọmọ kekeke ati obinrin; ṣugbọn ẹ máṣe sunmọ ẹnikan lara ẹniti àmi na wà; ẹ si bẹrẹ lati ibi mimọ́ mi. Bẹ̃ni nwọn bẹrẹ lati ọdọ awọn agbà ti o wà niwaju ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kékèké, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fọwọ́ kan àwọn tó ní àmì. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà tó wà níwájú tẹ́ḿpìlì.