Ezekiel 9:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di aláìmọ́, ẹ kó òkú eniyan kún gbọ̀ngàn rẹ̀, kí ẹ sì bọ́ síta.” Wọ́n bá bẹ́ sí ìgboro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn eniyan láàrin ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, ẹ sọ ile na di aimọ́, ẹ si fi okú kún agbala na: ẹ jade lọ. Nwọn si jade lọ, nwọn si pa enia ni ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ tẹ́ḿpìlì náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà. Ẹ lọ!” Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrin ìlú.