Ezekiel 9:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń pa àwọn eniyan, tí èmi nìkan dá dúró, mo dojúbolẹ̀, mo kígbe. Mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o óo pa gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Israẹli nítorí pé ò ń bínú sí Jerusalẹmu ni?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati nwọn npa wọn, ti a si fi emi silẹ, mo da oju mi bo ilẹ, mo si kigbe, mo si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha pa gbogbo awọn iyokù Israeli run, nipa dida irúnu rẹ jade sori Jerusalemu?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn mo dójú bolẹ̀, mo kígbe pé, “Áà! OLÚWA Ọlọ́run! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Ísírẹ́lì pẹ̀lú dída ìbínú gbígbónà rẹ sórí Jérúsálẹ́mù?”