Ezra 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àpapọ̀ àwọn ohun èlò wúrà ati fadaka yìí jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó lé irinwo (5,400). Ṣeṣibasari kó wọn lọ́wọ́ bí àwọn tí wọn kúrò ní oko ẹrú Babiloni ti ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ohun-èlo wura ati ti fadaka jẹ ẹgbẹtadilọgbọn. Gbogbo wọnyi ni Ṣeṣbassari mu goke wá pẹlu awọn igbekun ti a mu goke lati Babiloni wá si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn ún-ó-lé-irinwó (5,400). Ṣéṣíbáṣárì kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Bábílónì sí Jérúsálẹ́mù.