Ezra 1:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí Sáírúsì ọba Páṣíà wí pé: OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹ́ḿpìlì OLÚWA fún un ní Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà.