Ezra 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà, láti kọ́ tẹ́ḿpìlì OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ọlọ́run tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.