Ezra 10:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín, kí ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan náà ati kúrò lọ́dọ̀ àwọn obinrin àjèjì.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, ẹ jẹwọ fun Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin, ki ẹnyin ki o si mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ; ki ẹnyin ki o si ya ara nyin kuro ninu awọn enia ilẹ na, ati kuro lọdọ awọn ajeji obinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrin àwọn ìyàwó àjèjì yín.”