Ezra 10:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi pọ̀, ati pé àkókò òjò nìyí; a kò lè dúró ní gbangba báyìí. Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ohun tí a lè parí ní ọjọ́ kan tabi ọjọ́ meji, nítorí ohun tí a ṣe yìí, a ti ṣẹ̀ gan-an
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn enia pọ̀, igba òjo pupọ si ni, awa kò si le duro nita, bẹ̃ni eyi kì iṣe iṣẹ ọjọ kan tabi meji: nitoriti awa ti ṣẹ̀ pupọpupọ ninu ọ̀ran yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí ṣíbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró níta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrin ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí awọn nǹkan wọ̀nyí.