Ezra 10:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jẹ́ kí àwọn olórí wa dúró fún gbogbo àwùjọ yìí, kí wọ́n dá ọjọ́ tí àwọn tí wọ́n fẹ́ iyawo àjèjì ninu àwọn ìlú wa yóo wá, pẹlu àwọn àgbààgbà, ati àwọn adájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ibinu Ọlọrun lórí ọ̀rọ̀ yìí yóo fi kúrò lórí wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ki awọn olori wa ki o duro fun gbogbo ijọ enia, ki a si jẹ ki olukuluku ninu ilu wa ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, ki o wá ni wakati ti a da, ati awọn olori olukuluku ilu pẹlu wọn, ati awọn onidajọ wọn, titi a o fi yi ibinu kikan Ọlọrun wa pada kuro lọdọ wa nitori ọ̀ran yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa.