Ezra 10:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n pada ti oko ẹrú dé gba ìmọ̀ràn yìí. Nítorí náà, Ẹsira alufaa yan àwọn olórí ninu ìdílé wọn, wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Ní ọjọ́ kinni oṣù kẹwaa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ọmọ igbekun ṣe bẹ̃. Ati Esra, alufa, pẹlu awọn olori ninu awọn baba, nipa ile baba wọn, ati gbogbo wọn nipa orukọ wọn li a yà si ọ̀tọ, ti nwọn si joko li ọjọ kini oṣu kẹwa, lati wadi ọ̀ran na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n se fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Ẹ́sírà yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jòkóó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà,