Ezra 10:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí yóo fi di ọjọ́ kinni oṣù kinni, wọ́n ti parí ìwádìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ba gbogbo awọn ọkunrin ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe ṣe aṣepari, li ọjọ ekini oṣu ekini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kìn-ní-ní oṣù kìn-ní-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.