Ezra 10:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣekaniah ọmọ Jehieli, lati inu awọn ọmọ Elamu dahùn o si wi fun Esra pe, Awa ti ṣẹ̀ si Ọlọrun wa, ti awa ti mu ajeji obinrin lati inu awọn enia ilẹ na: sibẹ, ireti mbẹ fun Israeli nipa nkan yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣékáníáyà ọmọ Jéhíélì, ọ̀kan lára ìran Élámù, sọ fún Ẹ́sírà pé, Àwa ti jẹ́ aláìsọ̀ọ́tọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrin àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Ísírẹ́lì