Ezra 10:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ẹ́sírà padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jéhóhánánì ọmọ Élíásíbù. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìsòótọ́ àwọn ìgbèkùn.