Ezra 10:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà, ẹnikẹ́ni tí kò bá farahàn títí ọjọ́ mẹta, yóo pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pe ẹnikẹni ti kò ba wá niwọ̀n ijọ mẹta, gẹgẹ bi ìmọ awọn olori ati awọn agba, gbogbo ini rẹ̀ li a o jẹ, on tikararẹ̀ li a o si yà kuro ninu ijọ awọn enia ti a ti ko lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrin ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà, àti pé a ó lé òun fúnraaarẹ̀ jáde kúrò láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.