Ezra 2:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
WỌNYI li awọn ọmọ igberiko Juda ti o goke wa, lati inu igbèkun awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnessari, ọba Babiloni, ti ko lọ si Babiloni, ti nwọn si pada wá si Jerusalemu ati Juda, olukuluku si ilu rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wàyí o, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Júdà tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrin àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà. Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀,