Ezra 2:59 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Télì-Mélà, Télì-Háríṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò le fihàn pé àwọn ìdílé wọn ṣèẹ̀wá láti ìran Ísírẹ́lì: —