Ezra 2:62 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.