Ezra 2:65 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li aika iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹbinrin wọn, ti o jẹ ẹgbẹrindilẹgbãrin o din mẹtalelọgọta: igba akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin li o si wà ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.