Ezra 3:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli ti pada sí ìlú wọn, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI oṣu keje si pé, ti awọn ọmọ Israeli si wà ninu ilu wọnni, awọn enia na ko ara wọn jọ pọ̀ bi ẹnikan si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jérúsálẹ́mù.