Ezra 3:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọmọle si fi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ, nwọn mu awọn alufa duro ninu aṣọ wọn, nwọn mu ipè lọwọ, ati awọn ọmọ Lefi, awọn ọmọ Asafu mu kimbali lọwọ, lati ma yìn Oluwa gẹgẹ bi ìlana Dafidi ọba Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Léfì (Àwọn ọmọ Ásáfù) pẹ̀lú Kíńbálì, dúró ní ipò wọn láti yin OLÚWA, bí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti fi lélẹ̀.