Ezra 3:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé, “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.” Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si jùmọ kọrin lẹsẹsẹ lati yìn ati lati dupẹ fun Oluwa, nitoripe o ṣeun, ati pe anu rẹ̀ si duro lailai lori Israeli. Gbogbo enia si ho iho nla, nigbati nwọn nyìn Oluwa, nitoriti a fi ipilẹ ile Oluwa lelẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí OLÚWA: “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ sí Ísírẹ́lì dúró títí láé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin OLÚWA, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA lélẹ̀.