Ezra 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jeṣua, ọmọ Josadaki pẹlu àwọn alufaa ẹgbẹ́ rẹ̀ ati Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀ tún pẹpẹ Ọlọrun Israẹli kọ́, kí wọ́n baà lè máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, eniyan Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jeṣua ọmọ Jehosadaki si dide pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ awọn alufa, ati Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si tẹ́ pẹpẹ Ọlọrun Israeli, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun lori rẹ̀, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, enia Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run