Ezra 3:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n tẹ́ pẹpẹ náà sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn eniyan ibẹ̀; wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí rẹ̀ ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbe pẹpẹ na ka ipilẹ rẹ̀; nitori ẹ̀ru bà wọn nitori awọn enia ilẹ wọnni. Nwọn si rú ẹbọ ọrẹ sisun si Oluwa, ọrẹ ẹbọ sisun li owurọ ati li aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n ṣíbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ọrẹ sísun lórí rẹ̀ sí OLÚWA, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.