Ezra 3:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wọ́n rú àwọn ẹbọ wọnyi: ẹbọ àtìgbà-dégbà, ẹbọ oṣù titun, gbogbo ẹbọ ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati ti àwọn tí wọ́n bá fẹ́ rú ẹbọ àtinúwá sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin na nwọn si ru ẹbọ sisun igbagbogbo ati ti oṣu titun, ati ti gbogbo ajọ Oluwa, ti a si yà si mimọ́, ati ti olukuluku ti o fi tinu-tinu ru ẹbọ atinuwa si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti-gbà-dé-gbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLÚWA, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún OLÚWA.