Ezra 3:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti ọjọ́ kinni oṣù keje ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọn kò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọjọ ikini oṣu keje ni nwọn bẹ̀rẹ lati ma rú ẹbọ sisun si Oluwa. Ṣugbọn a kò ti ifi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ọrẹ sísun sí OLÚWA, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA lélẹ̀.