Ezra 3:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n fi owó sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń gbẹ́ òkúta ati fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. Wọ́n fún àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Tire ní oúnjẹ, ohun mímu, ati òróró; wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún igi kedari láti ilẹ̀ Lẹbanoni. Wọ́n ní kí wọ́n kó àwọn igi náà wá sí Jọpa ní etí òkun fún wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kirusi, ọba Pasia pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Ṣídónì àti Tírè, kí wọ́n ba à le è kó igi Sídà gba ti orí omi òkun láti Lébánónì wá sí Jópà, gẹ́gẹ́ bí Sáírúsì ọba Páṣíà ti pàṣẹ.