Ezra 3:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní oṣù keji ọdún keji tí wọ́n dé sí ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, pẹlu àwọn arakunrin wọn yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ti tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, láti máa bojútó iṣẹ́ ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù, Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì, Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn arákùnrin yóòkù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jérúsálẹ́mù) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Léfì tí ó tó ọmọ ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé OLÚWA.