Ezra 4:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Juu tí wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa ti lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí tún ìlú burúkú náà, tí ó kún fún ọ̀tẹ̀ kọ́. Wọ́n ti mọ odi rẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ parí ìpìlẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ọba ki o mọ̀ pe, awọn Ju ti o ti ọdọ rẹ wá si ọdọ wa, nwọn de Jerusalemu, nwọn nkọ́ ọlọtẹ ilu ati ilu buburu, nwọn si ti fi odi rẹ̀ lelẹ, nwọn si ti so ipilẹ rẹ̀ mọra pọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jérúsálẹ́mù wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.