Ezra 4:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kabiyesi, tí wọ́n bá fi lè kọ́ ìlú náà parí, tí wọ́n sì parí odi rẹ̀, wọn kò ní san owó ìṣákọ́lẹ̀ mọ́. Eléyìí yóo sì dín owó tí ń wọ àpò ọba kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ọba ki o mọ̀ nisisiyi pe, bi a ba kọ ilu yi, ti a si tun odi rẹ̀ gbe soke tan, nigbana ni nwọn kì o san owo ori, owo-bode, ati owo odè, ati bẹ̃ni nikẹhin yio si pa awọn ọba li ara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíwájú síi, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù.