Ezra 4:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki a le wá inu iwe-iranti awọn baba rẹ: bẹ̃ni iwọ o ri ninu iwe-iranti, iwọ o si mọ̀ pe, ọlọtẹ ni ilu yi, ti o si pa awọn ọba ati igberiko li ara, ati pe, nwọn ti ṣọtẹ ninu ikanna lati atijọ wá, nitori eyi li a fi fọ ilu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn àṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò ríi wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oní wàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run.