Ezra 4:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn tọ̀ Serubbabeli wá, ati awọn olori awọn baba, nwọn si wi fun wọn pe, ẹ jẹ ki awa ki o ba nyin kọle, nitoriti awa nṣe afẹri Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin; awa si nru ẹbọ si ọdọ rẹ̀, lati ọjọ Esarhaddoni, ọba Assuri, ẹniti o mu wa gòke wá ihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ṣérúbábélì àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i ti yín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà Ésáríhádónì ọba Ásíríà, tí ó mú wa wá síbi yìí.”