Ezra 4:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n ka ìwé ọba tán sí etígbọ̀ọ́ Rehumu ati Ṣimiṣai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, Rehumu ati Ṣimiṣai yára lọ sí Jerusalẹmu pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn sì fi ipá dá iṣẹ́ náà dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nigbati a ka atunkọ iwe Artasasta ọba niwaju Rehumu, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn, nwọn gòke lọ kankán si Jerusalemu, si ọdọ awọn Ju, nwọn si fi ipá pẹlu agbara mu wọn ṣiwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Aritaṣéṣéṣì sí Réhúmì àti Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.