Ezra 4:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Serubbabeli, ati Jeṣua ati iyokù ninu awọn olori awọn baba Israeli wi fun wọn pe, Kì iṣe fun awa pẹlu ẹnyin, lati jumọ kọ ile fun Ọlọrun wa; ṣugbọn awa tikarawa ni yio jùmọ kọle fun Oluwa Ọlọrun Israeli gẹgẹ bi Kirusi ọba, ọba Persia, ti paṣẹ fun wa,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ṣerubábélì, Jéṣúà àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Ẹ kò ní ipa pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bí Sáírúsì, ọba Páṣíà, ti pàṣẹ fún wa.”