Ezra 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ni àwọn wọnyi dìde: Biṣilamu, Mitiredati, Tabeeli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù. Wọ́n kọ̀wé sí ọba Pasia ní èdè Aremia, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ Artasasta ni Biṣlami, Mitredati, Tabeeli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ iyokù kọwe si Artasasta, ọba Persia: a si kọ iwe na li ède Siria, a si ṣe itumọ rẹ̀ li ède Siria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba Páṣíà, Bíṣílámì, Mítírédátì, Tábélì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ̀ rẹ̀ yóòkù kọ̀wé sí Aritaṣéṣéṣì. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Árámáíkì èdè Árámáíkì sì ní a fi kọ ọ́.