Ezra 5:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wolii Hagai ati wolii Sakaraya, ọmọ Ido, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Juu tí wọ́n wà ni Juda ati Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó jẹ́ orí fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ṢUGBỌN awọn woli, Haggai woli, ati Sekariah ọmọ Iddo, sọ asọtẹlẹ fun awọn Ju ti o wà ni Juda ati Jerusalemu li orukọ Ọlọrun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, láti ìrán Ìdó, sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn.