Ezra 5:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìdáhùn tí wọ́n fún wa ni pé: ‘Iranṣẹ Ọlọrun ọ̀run ati ayé ni wá. Tẹmpili tí à ń tún kọ́ yìí, ọba olókìkí kan ni ó kọ́ ọ parí ní ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni nwọn si fi èsi fun wa wipe, Iranṣẹ Ọlọrun ọrun on aiye li awa iṣe, awa si nkọ́ ile ti a ti kọ́ li ọdun pupọ wọnyi sẹhin, ti ọba nla kan ni Israeli ti kọ́, ti o si ti pari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa: Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹ́ḿpìlì ilé OLÚWA tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀.