Ezra 5:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó dá àwọn ohun èlò wúrà ati ti fadaka pada, tí Nebukadinesari kó ninu ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, lọ sí ilé oriṣa rẹ̀ ní Babiloni tẹ́lẹ̀. Gbogbo nǹkan wọnyi ni Kirusi ọba kó jáde kúrò ninu tẹmpili ní Babiloni, ó kó wọn lé Ṣeṣibasari lọ́wọ́, ẹni tí ó yàn ní gomina lórí Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu ohun èlo wura ati ti fàdaka ti ile Ọlọrun ti Nebukadnessari ko lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si mu lọ sinu tempili Babiloni, awọn na ni Kirusi ọba ko lati inu tempili Babiloni jade, a si fi wọn le ẹnikan lọwọ, orukọ ẹniti ijẹ Ṣeṣbassari, ẹniti on fi jẹ bãlẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lọ bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn-án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù. Kí wọn sì mú wá sí tẹ́ḿpílì ní Bábílónì Nígbà náà ọba Sáírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣesibásárì, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i Baálẹ̀,