Ezra 5:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún un nígbà náà pé, “Gba àwọn ohun èèlò wọnyi, kó wọn lọ sinu tẹmpili tí ó wà ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún tẹmpili náà kọ́ sí ojú ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun u pe, Kó ohun èlo wọnyi lọ, ki o fi wọn si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, ki o si mu ki a tun kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó sì sọ fún un pé, “Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù, pẹ̀lú kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.”