Ezra 5:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, kabiyesi, tí ó bá dára lójú rẹ, jẹ́ kí wọ́n lọ wo ìwé àkọsílẹ̀ ní Babiloni bí kìí bá ṣe nítòótọ́ ni Kirusi pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọrun kọ́ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí á mọ ohun tí o fẹ́ kí á ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, bi o ba wu ọba, jẹ ki a wá inu ile iṣura ọba ti o wà nibẹ ni Babiloni, bi o ba ri bẹ̃, pe Kirusi ọba fi aṣẹ lelẹ lati kọ ile Ọlọrun yi ni Jerusalemu, ki ọba ki o sọ eyi ti o fẹ fun wa nipa ọ̀ran yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Bábílónì láti rí bí ọba Ṣáírúsì fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.