Ezra 5:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ọba ki o mọ̀ pe, awa lọ si igberiko Judea si ile Ọlọrun ẹniti o tobi, ti a fi okuta nlanla kọ, a si tẹ igi si inu ogiri na, iṣẹ yi nlọ siwaju kánkán, o si nṣe rere li ọwọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Júdà, sí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alágbára. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsinmi, ó sì ń ní ìtẹ̀ṣíwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.